ÀSÀRÒ LÓRÍ BÍ A SE N FI YORÙBÁ TUKÒ ÈDÁ ÈDÈ TÀBÍ ÌGBÁSÀRÓ NÍ AKÉ 2019.

Ní ojó tí ó gbèyìn àjòdún Aké ti odún 2019, ètò tí àkórí rè dá lé orí bí a se n fi Yorùbá tukò èdá èdè tàbí ìgbásàró wáyé. Òjògbón Femi Taiwo, ìyá àfin Arinpe Adejumo àti Feyikemi Niyi-Olayinka jókò láti fi òrò jomitoro òrò pèlú Kola Tubosun. 

Kola Tubosun ní kí àwon òmòwé àti òjògbón yìí so òrò nípa ara won àti isé tí wón n se. 

Òjògbón Femi Taiwo so òrò nípa ara rè, léyìn náà, ó ka àkosílè láti inú ìwé pélébé tí ó wà ní owó rè. Nínú àwon òrò inú ìwé yíì ni ìsàlàyé bí èdè se pé irúurú. 

Ìyá àfin Arinpe Adejumo náà so ní kété nípa ara rè, àti oun tí àkòrí òrò ti òni túmò sí. Òun náà so òrò nípa bí èdè se pín sí orísirísi, àti bí Yorùbá se n se gbogbo isé tí àwon èdè yíì n se. Ó sì tún fa àkíyèsí wa sí bí ó se jé pé odún yìí ni ó pé igba odún tí Yorùbá jé kíko sílè. Ó tún mú enu ba bí àwon akéèkó kò se kín fé ka Yorùbá ní ilé ìwé gíga. 

Ìyá àfin Feyikemi Niyi-Olayinka fi èyónú rè hàn lórí bí àwon omo Yorùbá òde òní ò se gbé àsà ró mó; wón ti so àsà nù. Púpò nínú won ni kò ní orúko abínibí, tí o sì jé wípé orúko gèésì ni wón n jé. 

“Yorùbá kò le parun, sùgbón gbogbo wa ni a ní isé láti se.” Ìyá àfin Feyikemi Niyi-Olayinka so ní ìparí òrò rè. 

“Kílódé tí kíko àti títè síta ìwé Yorùbá kò se wópò bí ti àtijó?” Kola Tunbosun bèrè.

Ìyá àfin Àrínpé Adéjùmò dáùn pé ìwé Yorùbá sí n jé kíko àti títè, sùgbón àwon ènìyàn kò kín ràá. 

Léyìn àsàrò yí, tí ètò yí n sún mó ìparí, àwon bí mérin lára olùkópa Aké bèrè àwon ìbéèrè tí ó n rú won nínú, gbogbo wón síì jé dídàhùn.